Emi kò sọrọ ni ikọkọ ni ibi okùnkun aiye: Emi kò wi fun iru-ọmọ Jakobu pe, Ẹ wá mi lasan: emi Oluwa li o nsọ ododo, mo fi nkan wọnni ti o tọ́ hàn. Ko ara nyin jọ ki ẹ si wá; ẹ jọ sunmọ tosi, ẹnyin ti o salà ninu awọn orilẹ-ède: awọn ti o gbé igi ere gbigbẹ́ wọn kò ni ìmọ, nwọn si gbadura si ọlọrun ti ko le gba ni. Ẹ sọ ọ, ki ẹ si mu wá, lõtọ, ki nwọn ki o jọ gbimọ̀ pọ̀: tali o mu ni gbọ́ eyi lati igbãni wa? tali o ti sọ ọ lati igba na wá? emi Oluwa kọ? ko si Ọlọrun miran pẹlu mi; Ọlọrun ododo ati Olugbala; ko si ẹlomiran lẹhin mi.
Kà Isa 45
Feti si Isa 45
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 45:19-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò