Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye. Ẹniti o sọ àmi awọn eke di asan, ti o si bà awọn alafọṣẹ li ori jẹ, ti o dá awọn ọlọgbọn pada, ti o si sọ imọ̀ wọn di wère. Ti o fi ìdi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ̀ mulẹ, ti o si mu ìmọ awọn ikọ̀ rẹ̀ ṣẹ; ti o wi fun Jerusalemu pe, A o tẹ̀ ọ dó; ati fun gbogbo ilu Juda pe, A o kọ́ nyin, emi o si gbe gbogbo ahoro rẹ̀ dide: Ti o wi fun ibú pe, Gbẹ, emi o si mu gbogbo odò rẹ gbẹ. Ti o wi niti Kirusi pe, Oluṣọ-agutan mi ni, yío si mu gbogbo ifẹ mi ṣẹ: ti o wi niti Jerusalemu pe, A o kọ́ ọ: ati niti tempili pe, A o fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ.
Kà Isa 44
Feti si Isa 44
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 44:24-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò