Isa 44:14-17

Isa 44:14-17 YBCV

O bẹ́ igi kedari lu ilẹ fun ra rẹ̀, o si mu igi kipressi ati oaku, o si mu u le fun ra rẹ̀ ninu awọn igi igbó: o gbìn igi aṣi, ojò si mu u dagba. Nigbana ni yio jẹ ohun idana fun enia: nitori yio mu ninu wọn, yio si fi yá iná; lõtọ, o dá iná, o si din akara, lõtọ, o ṣe ọlọrun fun ra rẹ̀, o si nsìn i; o gbẹ ẹ li ere, o si nforibalẹ fun u. Apakan ninu rẹ̀ li o fi dá iná, apakan ninu rẹ̀ li o fi jẹ ẹran: o sun sisun, o si yo, o yá iná pẹlu, o si wipe, Ahã, ara mi gbona, mo ti ri iná. Iyokù rẹ̀ li o si fi ṣe ọlọrun, ani ere gbigbẹ́ rẹ̀, o foribalẹ fun u, o sìn i, o gbadura si i, o si wipe, Gbà mi; nitori iwọ li ọlọrun mi.