Isa 42:8-10

Isa 42:8-10 YBCV

Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹ̃ni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́. Kiyesi i, nkan iṣãju ṣẹ, nkan titun ni emi si nsọ: ki nwọn to hù, mo mu nyin gbọ́ wọn. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, iyìn rẹ̀ lati opin aiye, ẹnyin ti nsọkalẹ lọ si okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: erekùṣu, ati awọn ti ngbé inu wọn.