Isa 42:1-3

Isa 42:1-3 YBCV

WÒ iranṣẹ mi, ẹniti mo gbéro: ayànfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si; mo ti fi ẹmi mi fun u: on o mu idajọ wá fun awọn keferi. On kì yio kigbé, bẹ̃ni kì yio gbé ohùn soke, bẹ̃ni kì yio jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. Iyè fifọ́ ni on ki yio ṣẹ, owú ti nrú ẹ̃fin ni on kì yio pa: yio mu idajọ wá si otitọ.