Isa 40:21-23

Isa 40:21-23 YBCV

Ẹnyin kò ti mọ̀? ẹnyin kò ti gbọ́? a kò ti sọ fun nyin li atètekọṣe? kò iti yé nyin lati ipilẹṣẹ aiye wá? On ni ẹniti o joko lori òbíri aiye, gbogbo awọn ti ngbe ibẹ si dabi ẹlẹngà; ẹniti o ta ọrun bi ohun tita, ti o si nà wọn bi àgọ lati gbe. Ẹniti o nsọ awọn ọmọ-alade di ofo; o ṣe awọn onidajọ aiye bi asan.