Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi. Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ́ ni aginjù fun Ọlọrun wa. Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju: A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ. Ohùn na wipe, Kigbe. On si wipe, Igbe kini emi o ke? Gbogbo ẹran-ara ni koriko, gbogbo ogo rẹ̀ si dabi ìtànná igbẹ́: Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia. Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai.
Kà Isa 40
Feti si Isa 40
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 40:1-8
5 Days
Every good story has a plot twist—an unexpected moment that changes everything. One of the biggest plot twists in the Bible is the Christmas story. Over the next five days, we’ll explore how this one event changed the world and how it can change your life today.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò