Isa 35:3-6

Isa 35:3-6 YBCV

Ẹ mu ọwọ́ ailera le, ẹ si mu ẽkun ailera lokun. Ẹ sọ fun awọn alailaiyà pe, ẹ tujuka, ẹ má bẹ̀ru: wò o, Ọlọrun nyin o wá ti on ti ẹsan, Ọlọrun ti on ti igbẹsan; on o wá, yio si gbà nyin. Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi. Nigbana li awọn arọ yio fò bi agbọ̀nrin, ati ahọ́n odi yio kọrin: nitori omi yio tú jade li aginju, ati iṣàn omi ni ijù.