Isa 33:20-22

Isa 33:20-22 YBCV

Wo Sioni, ilu ajọ afiyesi wa: oju rẹ yio ri Jerusalemu ibugbe idakẹjẹ, agọ́ ti a kì yio tú palẹ mọ; kò si ọkan ninu ẽkàn rẹ ti a o ṣí ni ipò lai, bẹ̃ni kì yio si ọkan ninu okùn rẹ̀ ti yio já. Ṣugbọn nibẹ ni Oluwa ogo yio ri fun wa, bi ibi odò gbigbòro on odò ṣiṣàn; nibiti ọkọ̀ alajẹ̀ kì yio kọja, bẹ̃ni ọkọ̀ nlanla ki yio là a ja. Nitori Oluwa ni onidajọ wa, Oluwa li olofin wa, Oluwa li ọba wa; on o gbà wa là.