Isa 31:1-2

Isa 31:1-2 YBCV

EGBE ni fun awọn ti o sọkalẹ lọ si Egipti fun iranlọwọ; ti nwọn gbẹkẹlẹ ẹṣin, ti nwọn gbiyèle kẹkẹ́, nitoriti nwọn pọ̀: nwọn si gbẹkẹle ẹlẹṣin nitoriti nwọn li agbara jọjọ; ṣugbọn ti nwọn kò wò Ẹni-Mimọ Israeli, nwọn kò si wá Oluwa! Ṣugbọn on gbọ́n pẹlu, o si mu ibi wá, kì yio si dá ọ̀rọ rẹ̀ padà: on si dide si ile awọn oluṣe buburu, ati si oluranlọwọ awọn ti nṣiṣẹ aiṣedede.