Nitori awọn enia Sioni yio gbe Jerusalemu, iwọ kì yio sọkun mọ: yio ṣanu fun ọ gidigidi nigbati iwọ ba nkigbe; nigbati on ba gbọ́ ọ, yio dá ọ lohùn. Oluwa yio si fi onjẹ ipọnju, ati omi inira fun nyin, awọn olukọ́ni rẹ kì yio sápamọ́ mọ, ṣugbọn oju rẹ yio ri olukọ́ni rẹ̀: Eti rẹ o si gbọ́ ọ̀rọ kan lẹhin rẹ, wipe, Eyiyi li ọ̀na, ẹ ma rin ninu rẹ̀, nigbati ẹnyin bá yi si apa ọtún, tabi nigbati ẹnyin bá yi si apa òsi. Ẹnyin o si sọ ibora ere fadaka nyin wọnni di aimọ́, ati ọṣọ́ ere wura didà nyin wọnni: iwọ o sọ wọn nù bi ohun-aimọ́, iwọ o si wi fun u pe, Kuro nihinyi. On o si rọ̀ òjo si irugbin rẹ ti iwọ ti fọ́n si ilẹ: ati onjẹ ibísi ilẹ, yio li ọrá yio si pọ̀: li ọjọ na ni awọn ẹran rẹ yio ma jẹ̀ ni pápa oko nla. Awọn akọ-malu pẹlu, ati awọn ọmọ kẹtẹkẹtẹ ti ntulẹ yio jẹ oko didùn, ti a ti fi kọ̀nkọsọ ati atẹ fẹ. Ati lori gbogbo oke-nla giga, ati lori gbogbo oke kékèké ti o ga, ni odò ati ipa-omi yio wà li ọjọ pipa nla, nigbati ile-iṣọ́ wọnni bá wó. Imọ́lẹ oṣupa yio si dabi imọ́lẹ õrun, imọ́lẹ õrun yio si ràn ni iwọ̀n igbà meje, bi imọ́lẹ ọjọ meje, li ọjọ ti Oluwa dí yiya awọn enia rẹ̀, ti o si ṣe àwotán ọgbẹ ti a ṣá wọn.
Kà Isa 30
Feti si Isa 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 30:19-26
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò