Isa 30:18-19

Isa 30:18-19 YBCV

Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e. Nitori awọn enia Sioni yio gbe Jerusalemu, iwọ kì yio sọkun mọ: yio ṣanu fun ọ gidigidi nigbati iwọ ba nkigbe; nigbati on ba gbọ́ ọ, yio dá ọ lohùn.