Nitorina bayi li Ẹni-Mimọ Israeli wi, Nitoriti ẹnyin gàn ọ̀rọ yi, ti ẹnyin si gbẹkẹle ininilara on ìyapa, ti ẹnyin si gbe ara nyin lé e; Nitorina ni aiṣedede yi yio ri si nyin bi odi yiya ti o mura ati ṣubu, ti o tiri sode lara ogiri giga, eyiti wiwó rẹ̀ de lojijì, lojukanna. Yio si fọ́ ọ bi fifọ́ ohun-èlo amọ̀ ti a fọ́ tútu; ti a kò dasi: tobẹ̃ ti a kì yio ri apãdi kan ninu ẹfọ́ rẹ̀ lati fi fọ̀n iná li oju ãro, tabi lati fi bù omi ninu ikũdu. Nitori bayi ni Oluwa Jehofah, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Ninu pipada on sisimi li a o fi gbà nyin là; ninu didakẹjẹ ati gbigbẹkẹle li agbara nyin wà; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Bẹ̃kọ; nitori ẹṣin li a o fi sá; nitorina li ẹnyin o ṣe sá: ati pe, Awa o gùn eyi ti o lè sare; nitorina awọn ti yio lepa nyin yio lè sare. Ẹgbẹrun yio sá ni ibawi ẹnikan; ni ibawi ẹni marun li ẹnyin o sá: titi ẹnyin o fi kù bi àmi lori oke-nla, ati bi asia lori oke. Nitorina ni Oluwa yio duro, ki o le ṣe ore fun nyin, ati nitori eyi li o ṣe ga, ki o le ṣe iyọ́nu si nyin: nitori Oluwa li Ọlọrun idajọ: ibukun ni fun gbogbo awọn ti o duro dè e.
Kà Isa 30
Feti si Isa 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 30:12-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò