Isa 26:1-6

Isa 26:1-6 YBCV

LI ọjọ na li a o kọ orin yi ni ilẹ Juda; Awa ní ilu agbara; igbala li Ọlọrun yio yàn fun odi ati ãbo. Ẹ ṣi ilẹkun bodè silẹ, ki orilẹ-ède ododo ti nṣọ́ otitọ ba le wọ̀ ile. Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ. Ẹ gbẹkẹle Oluwa titi lai: nitori Oluwa Jehofa li apata aiyeraiye: Nitori o rẹ̀ awọn ti ngbe oke giga silẹ; ilu giga, o mu u wálẹ; o mu u wálẹ; ani si ilẹ; o mu u de inu ekuru. Ẹsẹ yio tẹ̀ ẹ mọlẹ, ani ẹsẹ awọn talaka, ati ìṣísẹ̀ awọn alaini.