Heb 9:26-28

Heb 9:26-28 YBCV

Bi bẹ̃kọ on kì bá ṣai mã jìya nigbakugba lati ipilẹ aiye: ṣugbọn nisisiyi li o fi ara hàn lẹ̃kanṣoṣo li opin aiye lati mu ẹ̀ṣẹ kuro nipa ẹbọ ara rẹ̀. Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ: Bẹ̃ni Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lẹ̃kanṣoṣo lati ru ẹ̀ṣẹ ọ̀pọlọpọ, yio farahan nigbakeji laisi ẹ̀ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rẹ̀ fun igbala.