Heb 7:20-28

Heb 7:20-28 YBCV

Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni. (Nitori a ti fi wọn jẹ alufa laisi ibura, nipa ẹniti o wi fun u pe, Oluwa bura, kì yio si ronupiwada, Iwọ ni alufa kan titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki:) Niwọn bẹ̃ ni Jesu ti di onigbọ̀wọ́ majẹmu ti o dara jù. Ati nitõtọ awọn pupọ̀ li a ti fi jẹ alufa, nitori nwọn kò le wà titi nitori ikú: Ṣugbọn on, nitoriti o wà titi lai, o ni oyè alufa ti a kò le rọ̀ nipò. Nitorina o si le gba wọn là pẹlu titi de opin, ẹniti o ba tọ̀ Ọlọrun wá nipasẹ rẹ̀, nitoriti o mbẹ lãye titi lai lati mã bẹ̀bẹ fun wọn. Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ; Ẹniti kò ni lati mã kọ́ rubọ lojojumọ, bi awọn olori alufa wọnni, fun ẹ̀ṣẹ ti ara rẹ̀ na, ati lẹhinna fun ti awọn enia: nitori eyi li o ti ṣe lẹ̃kanṣoṣo, nigbati o fi ara rẹ̀ rubọ. Nitoripe ofin a mã fi awọn enia ti o ni ailera jẹ olori alufa; ṣugbọn ọ̀rọ ti ibura, ti a ṣe lẹhin ofin, o fi Ọmọ jẹ, ẹniti a sọ di pipé titi lai.