O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki, Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin. Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki. Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀. (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun. Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni. (Nitori a ti fi wọn jẹ alufa laisi ibura, nipa ẹniti o wi fun u pe, Oluwa bura, kì yio si ronupiwada, Iwọ ni alufa kan titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki:) Niwọn bẹ̃ ni Jesu ti di onigbọ̀wọ́ majẹmu ti o dara jù.
Kà Heb 7
Feti si Heb 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 7:15-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò