Ṣugbọn, olufẹ, awa ni igbagbọ ohun ti o dara jù bẹ̃ lọ niti nyin, ati ohun ti o faramọ igbala, bi awa tilẹ nsọ bayi. Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe. Awa si fẹ ki olukuluku nyin ki o mã fi irú aisimi kanna hàn, fun ẹ̀kún ireti titi de opin: Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri. Nitori nigbati Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ̀ bura, wipe
Kà Heb 6
Feti si Heb 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 6:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò