Heb 4:6-9

Heb 4:6-9 YBCV

Nitorina bi o ti jẹ pe, o kù ki awọn kan wọ̀ inu rẹ̀, ati awọn ti a ti wasu ihinrere nã fun niṣãju kò wọ inu rẹ̀ nitori aigbọran: Ẹ̀wẹ, o yan ọjọ kan, o wi ninu Iwe Dafidi pe, Loni, lẹhin igba pipẹ bẹ̃; bi a ti wi niṣãju, Loni bi ẹnyin ba gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le. Nitori ibaṣepe Joṣua ti fun wọn ni isimi, on kì ba ti sọrọ nipa ọjọ miran lẹhinna. Nitorina isimi kan kù fun awọn enia Ọlọrun.