Nitori o ti sọ nibikan niti ọjọ keje bayi pe, Ọlọrun si simi ni ijọ keje kuro ninu iṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ati nihinyi ẹ̀wẹ pe, Nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi. Nitorina bi o ti jẹ pe, o kù ki awọn kan wọ̀ inu rẹ̀, ati awọn ti a ti wasu ihinrere nã fun niṣãju kò wọ inu rẹ̀ nitori aigbọran: Ẹ̀wẹ, o yan ọjọ kan, o wi ninu Iwe Dafidi pe, Loni, lẹhin igba pipẹ bẹ̃; bi a ti wi niṣãju, Loni bi ẹnyin ba gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le. Nitori ibaṣepe Joṣua ti fun wọn ni isimi, on kì ba ti sọrọ nipa ọjọ miran lẹhinna. Nitorina isimi kan kù fun awọn enia Ọlọrun. Nitoripe ẹniti o ba bọ́ sinu isimi rẹ̀, on pẹlu simi kuro ninu iṣẹ tirẹ̀, gẹgẹ bi Ọlọrun ti simi kuro ni tirẹ̀.
Kà Heb 4
Feti si Heb 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 4:4-10
8 Days
What is rest? What does it mean to enter into God’s rest? What exactly are we resting from? As we journey through Part Two of Nine devotional plans walking us through the book of Hebrews, we discover how God defines rest, how we enter this rest and how we grow from this position of rest.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò