Heb 3:15-19

Heb 3:15-19 YBCV

Nigbati a nwipe, Loni bi ẹnyin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ máṣe sé ọkàn nyin le, bi igba imunibinu. Nitori awọn tani bi nyin ninu nigbati nwọn gbọ́? Ki ha iṣe gbogbo awọn ti o ti ipasẹ Mose jade lati Egipti wá? Awọn tali o si binu si fun ogoji ọdún? Ki ha iṣe si awọn ti o dẹṣẹ, okú awọn ti o sun li aginjù? Awọn tali o si bura fun pe nwọn kì yio wọ̀ inu isimi on, bikoṣe fun awọn ti kò gbọran? Awa si ri pe nwọn kò le wọ̀ inu rẹ̀ nitori aigbagbọ́.