Heb 2:1-3

Heb 2:1-3 YBCV

NITORINA o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan. Nitori bi ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbà ẹsan ti o tọ́; Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́