Heb 12:9-13

Heb 12:9-13 YBCV

Pẹlupẹlu awa ni baba wa nipa ti ara ti o ntọ́ wa, awa si mbù ọlá fun wọn: awa kì yio kuku tẹriba fun Baba awọn ẹmí ki a si yè? Nitori nwọn tọ́ wa fun ọjọ diẹ bi o ba ti dara loju wọn; ṣugbọn on fun ère wa, ki awa ki o le ṣe alabapin ìwa mimọ́ rẹ̀. Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ̀ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ̀, ani eso ododo. Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera; Ki ẹ si ṣe ipa-ọna ti o tọ fun ẹsẹ nyin, ki eyiti o rọ má bã kuro lori iké ṣugbọn ki a kuku wo o san.