Ẹnyin si ti gbagbé ọ̀rọ iyanju ti mba nyin sọ bi ọmọ pe, Ọmọ mi, má ṣe alainani ibawi Oluwa, ki o má si ṣe rẹwẹsi nigbati a ba nti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wi: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi, a si mã nà olukuluku ọmọ ti o gbà. Ẹ mã mu suru labẹ ibawi: Ọlọrun mba nyin lo bi ọmọ ni; nitoripe ọmọ wo ni mbẹ ti baba ki ibawi? Ṣugbọn bi ẹnyin ba wà li aisi ibawi, ninu eyiti gbogbo enia ti jẹ alabapin, njẹ ọmọ àle ni nyin, ẹ kì isi iṣe ọmọ. Pẹlupẹlu awa ni baba wa nipa ti ara ti o ntọ́ wa, awa si mbù ọlá fun wọn: awa kì yio kuku tẹriba fun Baba awọn ẹmí ki a si yè? Nitori nwọn tọ́ wa fun ọjọ diẹ bi o ba ti dara loju wọn; ṣugbọn on fun ère wa, ki awa ki o le ṣe alabapin ìwa mimọ́ rẹ̀. Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ̀ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ̀, ani eso ododo. Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera; Ki ẹ si ṣe ipa-ọna ti o tọ fun ẹsẹ nyin, ki eyiti o rọ má bã kuro lori iké ṣugbọn ki a kuku wo o san.
Kà Heb 12
Feti si Heb 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 12:5-13
5 Days
Need more of God's grace, favor, and blessing? Then pray these five simple prayers of humility, asking the Lord to favor you and help you. He will answer your prayer; He gives grace to the humble! And if you humble yourself before the Lord, He will lift you up.
7 Days
In a crowded Christmas season, most of us feel the stress and anxiety of family relationships, financial pressure, hasty decisions, and disappointed expectations. So go ahead. Take a breath. Start this Life.Church Bible Plan and realize the weight we feel may be something God never asked us to carry. How about we let go of the baggage? Let’s travel light.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò