Heb 12:25-29

Heb 12:25-29 YBCV

Kiyesi i, ki ẹ máṣe kọ̀ ẹniti nkilọ. Nitori bi awọn wọnni kò ba bọ́ nigbati nwọn kọ̀ ẹniti nkilọ li aiye, melomelo li awa kì yio bọ́ awa ti o pẹhinda si ẹniti nkilọ lati ọrun wá: Ohùn ẹniti o mì aiye nigbana: ṣugbọn nisisiyi o ti ṣe ileri, wipe, Lẹ̃kan si i emi kì yio mì kìki aiye nikan, ṣugbọn ọrun pẹlu. Ati ọ̀rọ yi, Lẹ̃kan si i, itumọ rẹ̀ ni mimu awọn ohun wọnni ti a nmì kuro, bi ohun ti a ti da, ki awọn ohun wọnni ti a kò le mì le wà sibẹ. Nitorina bi awa ti ngbà ilẹ ọba ti a kò le mì, ẹ jẹ ki a ni ore-ọfẹ nipa eyiti awa le mã sin Ọlọrun ni itẹwọgbà pẹlu ọ̀wọ ati ibẹru rẹ̀. Nitoripe Ọlọrun wa, iná ti ijonirun ni.