Heb 12:18-21

Heb 12:18-21 YBCV

Nitori ẹnyin kò wá si òke, ti a le fi ọwọ kàn, ati si iná ti njó, ati si iṣúdùdu ati òkunkun, ati iji, Ati iró ipè, ati ohùn ọ̀rọ, eyiti awọn ti o gbọ́ bẹ̀bẹ pe, ki a máṣe sọ ọ̀rọ si i fun wọn mọ́: Nitoripe ara wọn kò le gbà ohun ti o palaṣẹ, Bi o tilẹ jẹ ẹranko li o farakan òke na, a o sọ ọ li okuta, tabi a o gún u li ọ̀kọ pa. Iran na si lẹrù tobẹ̃, ti Mose wipe, ẹ̀ru bà mi gidigidi mo si warìri.