Heb 11:7-8

Heb 11:7-8 YBCV

Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́. Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè.