NJẸ igbagbọ́ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri. Nitori ninu rẹ̀ li awọn alàgba ti ni ẹri rere. Nipa igbagbọ́ li a mọ̀ pe a ti da aiye nipa ọ̀rọ Ọlọrun; nitorina ki iṣe ohun ti o hàn li a fi dá ohun ti a nri. Nipa igbagbọ́ ni Abeli ru ẹbọ si Ọlọrun ti o san ju ti Kaini lọ, nipa eyiti a jẹri rẹ̀ pe olododo ni, Ọlọrun si njẹri ẹ̀bun rẹ̀: ati nipa rẹ̀ na, bi o ti kú ni, o nfọhùn sibẹ̀. Nipa igbagbọ́ li a ṣí Enoku nipò pada ki o máṣe ri ikú; a kò si ri i, nitoriti Ọlọrun ṣí i nipò pada: nitori ṣaju iṣipopada rẹ̀, a jẹrí yi si i pe o wù Ọlọrun. Ṣugbọn li aisi igbagbọ́ ko ṣe iṣe lati wù u; nitori ẹniti o ba ntọ̀ Ọlọrun wá kò le ṣai gbagbọ́ pe o mbẹ, ati pe on ni olusẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a. Nipa igbagbọ́ ni Noa, nigbati Ọlọrun kilọ ohun ti koi ti iri fun u, o bẹru Ọlọrun, o si kàn ọkọ̀ fun igbala ile rẹ̀, nipa eyiti o dá aiye lẹbi, o si di ajogún ododo ti iṣe nipa igbagbọ́. Nipa igbagbọ́ ni Abrahamu, nigbati a ti pè e lati jade lọ si ibi ti on yio gbà fun ilẹ-ini, o gbọ́, o si jade lọ, lai mọ̀ ibiti on nrè. Nipa igbagbọ́ li o ṣe atipo ni ilẹ ileri, bi ẹnipe ni ilẹ àjeji, o ngbé inu agọ́, pẹlu Isaaki ati Jakọbu, awọn ajogún ileri kanna pẹlu rẹ̀: Nitoriti o nreti ilu ti o ni ipilẹ̀; eyiti Ọlọrun tẹ̀do ti o si kọ́.
Kà Heb 11
Feti si Heb 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 11:1-10
3 Awọn ọjọ
Ìrìn-àjò Kristẹni jẹ́ èyí tí a kò ti rí Ọlọ́run lójú-kojú, a máa ń bá A ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo láti wu Ọlọ́run nínú ìrìn wa pẹ̀lú Rẹ̀ ni ìgbàgbọ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé a kò lè rí I pẹ̀lú ojú wa nípa tara. À ń gbọ́ Ọ nípa ìgbàgbọ́, à ń bá A sọ̀rọ̀ nípa Ìgbàgbọ́, a sì ń tọ̀ Ọ́ lọ nínú àdúrà nípa ìgbàgbọ́.
5 Awọn ọjọ
Gbigbe irin ajo lọ si ohun ti a npe ni igbagbọ ti Bibeli A wo ìgbésí ayé Ábúráhámù, baba ńlá ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì, àti díẹ̀ lára àwọn ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́ run, àwọn ìtọ́ ni wo ló ní láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́ run tí ó sì ṣègbọràn sí ohun tí Ọlọ́ run béèrè lọ́ wọ́ rẹ̀? Ti kii ba ṣe bẹ, awọn abajade odi wa fun iyapa rẹ?
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò