Heb 10:8-10

Heb 10:8-10 YBCV

Nigbati o wi ni iṣaju pe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ati ẹbọ sisun, ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ni iwọ kò ni inu didun si wọn (awọn eyiti a nrú gẹgẹ bi ofin). Nigbana ni o wipe, Kiyesi i, Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. O mu ti iṣaju kuro, ki o le fi idi ekeji mulẹ. Nipa ifẹ na li a ti sọ wa di mimọ́ nipa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ̃kanṣoṣo.