Heb 10:5-14

Heb 10:5-14 YBCV

Nitorina nigbati o wá si aiye, o wipe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ṣugbọn ara ni iwọ ti pèse fun mi: Ẹbọ sisun ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ ni iwọ kò ni inu didùn si. Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i (ninu iwe-kiká nì li a gbé kọ ọ nipa ti emi) Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. Nigbati o wi ni iṣaju pe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ati ẹbọ sisun, ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ni iwọ kò ni inu didun si wọn (awọn eyiti a nrú gẹgẹ bi ofin). Nigbana ni o wipe, Kiyesi i, Mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. O mu ti iṣaju kuro, ki o le fi idi ekeji mulẹ. Nipa ifẹ na li a ti sọ wa di mimọ́ nipa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ̃kanṣoṣo. Ati olukuluku alufa si nduro li ojojumọ́ o nṣe ìsin, o si nṣe ẹbọ kanna nigbakugba, ti kò le mu ẹ̀ṣẹ kuro lai: Ṣugbọn on, lẹhin igbati o ti ru ẹbọ kan fun ẹ̀ṣẹ titi lai, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; Lati igbà na lọ, ó nreti titi a o fi fi awọn ọtá rẹ̀ ṣe apoti itisẹ rẹ̀. Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai.