Heb 10:14-22

Heb 10:14-22 YBCV

Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai. Ẹmí Mimọ́ si njẹri fun wa pẹlu: nitori lẹhin ti o ti wipe, Eyi ni majẹmu ti emi ó ba wọn dá lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si wọn li ọkàn, inu wọn pẹlu li emi o si kọ wọn si; Ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́. Ṣugbọn nibiti imukuro iwọnyi ba gbé wà, irubọ fun ẹ̀ṣẹ kò si mọ́. Ará, njẹ bi a ti ni igboiya lati wọ̀ inu ibi mimọ́ nipasẹ ẹ̀jẹ Jesu, Nipa ọ̀na titun ati ãye, ti o yà si mimọ́ fun wa, ati lati kọja aṣọ ikele nì, eyini ni, ara rẹ̀; Ati bi a ti ni alufa giga lori ile Ọlọrun; Ẹ jẹ ki a fi otitọ ọkàn sunmọ tosi ni ẹ̀kún igbagbọ́, ki a si wẹ̀ ọkàn wa mọ́ kuro ninu ẹri-ọkàn buburu, ki a si fi omi mimọ́ wẹ̀ ara wa nù.