O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ. Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi? Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u. Ati niti awọn angẹli, o wipe, Ẹniti o dá awọn angẹli rẹ̀ li ẹmí, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ li ọwọ́ iná. Ṣugbọn niti Ọmọ li o wipe, Itẹ́ rẹ, Ọlọrun, lai ati lailai ni; ọpá alade ododo li ọpá alade ijọba rẹ. Iwọ fẹ ododo, iwọ si korira ẹ̀ṣẹ; nitorina li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi oróro ayọ̀ yan ọ jù awọn ẹgbẹ rẹ lọ. Ati Iwọ, Oluwa, li atetekọṣe li o ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; awọn ọrun si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ: Nwọn ó ṣegbe; ṣugbọn iwọ ó wà sibẹ, gbogbo wọn ni yio si gbó bi ẹwu; Ati bi aṣọ ni iwọ o si ká wọn, a o si pàrọ wọn: ṣugbọn bakanna ni iwọ, ọdún rẹ kì yio si pin. Ṣugbọn ewo ninu awọn angẹli li o sọ nipa rẹ̀ ri pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?
Kà Heb 1
Feti si Heb 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Heb 1:4-14
7 Awọn ọjọ
Bíbélì jẹ iwe èto itan bi Ọlọrun ṣe fi ara rẹ hàn fún ẹdá ènìyàn. Ojẹ àlàyé bi Ọlọrun to fẹran iṣẹda rẹ, pẹlú ipò ìṣubú wọn, síbẹ o nọwọ rẹ lati fi kanwo, lati gb'awọn lá, wo wọn sàn ati tuwọn ni ide Kúrò lọwọ ikú ati iparun ayérayé. Èrò idi fún ẹkọ yi ni lati ran wa lọwọ ki ale mọ̀ Ọlọrun baba lati inu Kristi Ọmọ.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò