Gẹgẹ bi ọ̀rọ ti mo ba nyin dá majẹmu nigbati ẹnyin ti Egipti jade wá, bẹ̃ni ẹmi mi wà lãrin nyin: ẹ máṣe bẹ̀ru. Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, Ẹ̃kan ṣa, nigbà diẹ si i, li emi o mì awọn ọrun, ati aiye, ati okun, ati iyàngbẹ ilẹ. Emi o si mì gbogbo orilẹ-ède, ifẹ gbogbo orilẹ-ède yio si de: emi o si fi ogo kún ile yi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Temi ni fàdakà, temi si ni wurà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ogo ile ikẹhìn yi yio pọ̀ jù ti iṣãju lọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nihinyi li emi o si fi alafia fun ni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Kà Hag 2
Feti si Hag 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Hag 2:5-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò