Gẹn 9:7-29

Gẹn 9:7-29 YBCV

Ati ẹnyin, ki ẹnyin ki o ma bí si i; ki ẹ si ma rẹ̀ si i, ki ẹ si ma gbá yìn lori ilẹ, ki ẹ si ma rẹ̀ ninu rẹ̀. Ọlọrun si wi fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, pe, Ati emi, kiye si i, emi ba nyin dá majẹmu mi, ati awọn irú-ọmọ nyin lẹhin nyin; Ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin; ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ati ẹranko aiye pélu nyin; lati gbogbo awọn ti o ti inu ọkọ̀ jade, titi o fi de gbogbo ẹranko aiye. Emi o si ba nyin dá majẹmu mi; a ki yio si fi kíkun-omi ké gbogbo ẹdá kuro mọ́; bẹ̃ni kíkun-omi ki yio sí mọ́, lati pa aiye run. Ọlọrun si wipe, Eyiyi li àmi majẹmu mi ti mo ba nyin dá, ati gbogbo ẹdá alãye ti o wà pẹlu nyin, fun atirandiran: Mo fi òṣumare mi si awọsanma, on ni yio si ma ṣe àmi majẹmu mi ti mo ba aiye dá. Yio si ṣe, nigbati mo ba mu awọsanma wá si ori ilẹ, a o si ma ri òṣumare na li awọsanma: Emi o si ranti majẹmu mi, ti o wà lãrin emi ati ẹnyin, ati gbogbo ọkàn alãye ni gbogbo ẹdá; omi ki yio si di kíkun mọ́ lati pa gbogbo ẹdá run. Òṣumare na yio si wà li awọsanma; emi o si ma wò o, ki emi le ma ranti majẹmu lailai ti o wà pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wà ninu gbogbo ẹdá ti o wà li aiye. Ọlọrun si wi fun Noa pe, Eyiyi li àmi majẹmu na, ti mo ba ara mi ati ẹdá gbogbo ti o wà lori ilẹ dá. Awọn ọmọ Noa, ti o si jade ninu ọkọ̀ ni Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti: Hamu si ni baba Kenaani. Awọn mẹta wọnyi li ọmọ Noa: lati ọdọ wọn li a gbé ti tàn ká gbogbo aiye. Noa si bẹ̀rẹ si iṣe àgbẹ, o si gbìn ọgbà-àjara: O si mu ninu ọti-waini na, o mu amupara; o si tú ara rẹ̀ si ìhoho ninu agọ́ rẹ̀. Hamu, baba Kenaani, si ri ìhoho baba rẹ̀, o si sọ fun awọn arakunrin rẹ̀ meji lode. Ati Ṣemu ati Jafeti mu gọgọwu, nwọn si fi le ejika awọn mejeji, nwọn si fi ẹhin rìn, nwọn si bò ìhoho baba wọn; oju wọn si wà lẹhin; nwọn kò si ri ìhoho baba wọn. Noa si jí kuro li oju ọti-waini rẹ̀, o si mọ̀ ohun ti ọmọ rẹ̀ kekere ṣe si i. O si wipe, Egbe ni fun Kenaani; iranṣẹ awọn iranṣẹ ni yio ma ṣe fun awọn arakunrin rẹ̀. O si wipe, Olubukun li OLUWA Ọlọrun Ṣemu; Kenaani yio ma ṣe iranṣẹ rẹ̀. Ọlọrun yio mu Jafeti gbilẹ, yio si ma gbé agọ́ Ṣemu; Kenaani yio si ma ṣe iranṣẹ wọn. Noa si wà ni irinwo ọdun o din ãdọta, lẹhin ìkún-omi. Gbogbo ọjọ́ Noa jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí ãdọta: o si kú.