ỌLỌRUN si sure fun Noa, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ ma bí si i, ẹ si ma rẹ̀, ki ẹ si kún aiye. Ati ìbẹru nyin, ati ìfoya nyin, yio ma wà lara gbogbo ẹranko aiye, ati lara gbogbo ẹiyẹ oju-ọrun, ati lara gbogbo ohun ti nrakò ni ilẹ, ati lara gbogbo ẹja okun; ọwọ́ nyin li a fi wọn lé. Gbogbo ohun alãye, ti nrakò, ni yio ma ṣe onjẹ fun nyin; gẹgẹ bi eweko tutu ni mo fi ohun gbogbo fun nyin. Kìki ẹran pẹlu ẹmi rẹ̀, ani ẹ̀jẹ rẹ̀, on li ẹnyin kò gbọdọ jẹ. Nitõtọ ẹ̀jẹ nyin ani ẹmi nyin li emi o si bère; lọwọ gbogbo ẹranko li emi o bère rẹ̀, ati lọwọ enia, lọwọ arakunrin olukuluku enia li emi o bère ẹmi enia. Ẹnikẹni ti o ba ta ẹ̀jẹ enia silẹ, lati ọwọ́ enia li a o si ta ẹ̀jẹ rẹ̀ silẹ: nitoripe li aworan Ọlọrun li o dá enia.
Kà Gẹn 9
Feti si Gẹn 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 9:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò