Gẹn 49:2-10

Gẹn 49:2-10 YBCV

Ẹ kó ara nyin jọ, ki ẹ si gbọ́, ẹnyin ọmọ Jakobu; ki ẹ si fetisi ti Israeli baba nyin. Reubeni, iwọ li akọ́bi mi, agbara mi, ati ipilẹṣẹ ipá mi, titayọ ọlá, ati titayọ agbara. Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi. Simeoni on Lefi, arakunrin ni nwọn; ohun-èlo ìka ni idà wọn. Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì. Ifibú ni ibinu wọn, nitori ti o rorò; ati ikannu wọn, nitori ti o ní ìka: emi o pin wọn ni Jakobu, emi o si tú wọn ká ni Israeli. Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ. Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide? Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.