Akokò Israeli si sunmọ-etile ti yio kú: o si pè Josefu ọmọ rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bi emi ba ri ojurere li oju rẹ, jọ̃, fi ọwọ́ rẹ si abẹ itan mi, ki o si ṣe ãnu ati otitọ fun mi; emi bẹ̀ ọ, máṣe sin mi ni Egipti. Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi. O si wipe, Bura fun mi. On si bura fun u. Israeli si tẹriba lori akete.
Kà Gẹn 47
Feti si Gẹn 47
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 47:29-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò