Gẹn 45:4-7

Gẹn 45:4-7 YBCV

Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi bẹ̀ nyin ẹ sunmọ ọdọ mi. Nwọn si sunmọ ọ. O si wi pe, Emi ni Josefu, arakunrin nyin, ti ẹnyin tà si Egipti. Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là. Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè. Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là.