Gẹn 45:21-23

Gẹn 45:21-23 YBCV

Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃: Josefu si fi kẹkẹ́-ẹrù fun wọn, gẹgẹ bi aṣẹ Farao, o si fi onjẹ ọ̀na fun wọn. O fi ìparọ-aṣọ fun gbogbo wọn fun olukuluku wọn; ṣugbọn Benjamini li o fi ọdunrun owo fadaka fun, ati ìparọ-aṣọ marun. Bayi li o si ranṣẹ si baba rẹ̀; kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ohun rere Egipti, ati abo-kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ọkà ati àkara ati onjẹ fun baba rẹ̀ li ọ̀na.