Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já. Li ọdún meje ọ̀pọ nì, ilẹ si so eso ni ikunwọ-ikunwọ. O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀. Josefu si kó ọkà jọ bi iyanrin okun lọ̀pọlọpọ; titi o fi dẹkun ati mã ṣirò; nitori ti kò ní iye. A si bí ọmọkunrin meji fun Josefu, ki ọdún ìyan na ki o to dé, ti Asenati bí fun u, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si sọ orukọ akọ́bi ni Manasse: wipe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ́ mi, ati gbogbo ile baba mi. Orukọ ekeji li o si sọ ni Efraimu: nitori Ọlọrun ti mu mi bisi i ni ilẹ ipọnju mi. Ọdún meje ọ̀pọ na ti o wà ni ilẹ Egipti si pari. Ọdún meje ìyan si bẹ̀rẹ si dé, gẹgẹ bi Josefu ti wi: ìyan na si mú ni ilẹ gbogbo; ṣugbọn ni gbogbo ilẹ Egipti li onjẹ gbé wà. Nigbati ìyan mú ni gbogbo ilẹ Egipti, awọn enia kigbe onjẹ tọ̀ Farao: Farao si wi fun gbogbo awọn ara Egipti pe, Ẹ ma tọ̀ Josefu lọ; ohunkohun ti o ba wi fun nyin ki ẹ ṣe. Ìyan na si wà lori ilẹ gbogbo: Josefu si ṣí gbogbo ile iṣura silẹ, o si ntà fun awọn ara Egipti; ìyan na si nmú si i ni ilẹ Egipti. Ilẹ gbogbo li o si wá si Egipti lati rà onjẹ lọdọ Josefu; nitori ti ìyan na mú gidigidi ni ilẹ gbogbo.
Kà Gẹn 41
Feti si Gẹn 41
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 41:46-57
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò