Gẹn 40:20-23

Gẹn 40:20-23 YBCV

O si ṣe ni ijọ́ kẹta, ti iṣe ọjọ́ ibí Farao, ti o sè àse fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ gbogbo: o si gbé ori olori agbọti soke ati ti olori awọn alasè lãrin awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. O si tun mú olori agbọti pada si ipò rẹ̀; on si fi ago lé Farao li ọwọ́: Ṣugbọn olori alasè li o sorọ̀: bi Josefu ti tumọ̀ alá na fun wọn. Ṣugbọn olori agbọti kò ranti Josefu, o gbagbe rẹ̀.