Gẹn 38:25-30

Gẹn 38:25-30 YBCV

Nigbati a si mú u jade, o ranṣẹ si baba ọkọ rẹ̀ pe, ọkunrin ti o ní nkan wọnyi li emi yún fun: o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mọ̀ wọn, ti tani nkan wọnyi, èdidi, ati okùn, ati ọpá. Judah si jẹwọ, o si wipe, O ṣe olododo jù mi lọ; nitori ti emi kò fi i fun Ṣela ọmọ mi. On kò si mọ̀ ọ mọ́ lai. O si ṣe li akokò ti o nrọbí, si kiyesi i, ìbejì wà ni inu rẹ̀. O si ṣe nigbati o nrọbí, ti ọkan yọ ọwọ́ jade: iyãgba si mú okùn ododó o so mọ́ ọ li ọwọ́, o wipe, Eyi li o kọ jade. O si ṣe, bi o ti fà ọwọ́ rẹ̀ pada, si kiyesi i, aburo rẹ̀ jade: o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yà? yiyà yi wà li ara rẹ, nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Peresi: Nikẹhin li arakunrin rẹ̀ jade, ti o li okùn ododó li ọwọ́ rẹ̀: a si sọ orukọ rẹ̀ ni Sera.