Gẹn 38:1-11

Gẹn 38:1-11 YBCV

O SI ṣe li akokò na, ni Judah sọkalẹ lọ kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, o si yà sọdọ ara Adullamu kan, orukọ ẹniti ijẹ́ Hira. Judah si ri ọmọbinrin ara Kenaani kan nibẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Ṣua; o si mú u, o si wọle tọ̀ ọ. O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Eri. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Onani. O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣela: o wà ni Kesibu, nigbati o bí i. Judah si fẹ́ aya fun Eri akọ́bi rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Tamari. Eri akọ́bi Judah si ṣe enia buburu li oju OLUWA; OLUWA si pa a. Judah si wi fun Onani pe, Wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ lọ, ki o si ṣú u li opó, ki o si bimọ si ipò arakunrin rẹ. Onani si mọ̀ pe, irú-ọmọ ki yio ṣe tirẹ̀; o si ṣe bi o ti wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ̀ lọ, o si dà a silẹ, ki o má ba fi irú-ọmọ fun arakunrin rẹ̀. Ohun ti o si ṣe buru loju OLUWA, nitori na li OLUWA pa a pẹlu. Nigbana ni Judah wi fun Tamari aya ọmọ rẹ̀ pe, Joko li opó ni ile baba rẹ, titi Ṣela ọmọ mi o fi dàgba: nitori o wipe, Ki on má ba kú pẹlu, bi awọn arakunrin rẹ̀. Tamari si lọ, o si joko ni ile baba rẹ̀.