Gẹn 37:31-34

Gẹn 37:31-34 YBCV

Nwọn si mú ẹ̀wu Josefu, nwọn si pa ọmọ ewurẹ kan, nwọn si rì ẹ̀wu na sinu ẹ̀jẹ na. Nwọn si fi ẹ̀wu alarabara aṣọ na ranṣẹ, nwọn si mú u tọ̀ baba wọn wá; nwọn si wipe, Eyi li awa ri: mọ̀ nisisiyi bi ẹ̀wu ọmọ rẹ ni, bi on kọ́. On si mọ̀ ọ, o si wipe, Ẹ̀wu ọmọ mi ni; ẹranko buburu ti pa a jẹ; li aiṣe aniani, a ti fà Josefu ya pẹrẹpẹrẹ. Jakobu si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si ṣọ̀fọ ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ pupọ̀.