JAKOBU si gbé oju rẹ̀ soke, o si wò, si kiyesi i, Esau dé, ati irinwo ọkunrin pẹlu rẹ̀. On si pín awọn ọmọ fun Lea, ati fun Rakeli, ati fun awọn iranṣẹbinrin mejeji. O si tì awọn iranṣẹbinrin ati awọn ọmọ wọn ṣaju, ati Lea ati awọn ọmọ rẹ̀ tẹle wọn, ati Rakeli ati Josefu kẹhin. On si kọja lọ siwaju wọn, o si wolẹ li ẹrinmeje titi o fi dé ọdọ arakunrin rẹ̀. Esau si sure lati pade rẹ̀, o si gbá a mú, o si rọmọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu: nwọn si sọkun.
Kà Gẹn 33
Feti si Gẹn 33
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 33:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò