O si dide li oru na, o si mú awọn aya rẹ̀ mejeji, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ mejeji, ati awọn ọmọ rẹ̀ mọkọkanla, o si kọja iwọdò Jabboku. O si mú wọn, o si rán wọn si oke odò na, o si rán ohun ti o ní kọja si oke odò. O si kù Jakobu nikan; ọkunrin kan si mbá a jijakadi titi o fi di afẹmọ́jumọ. Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi. O si wipe, Jẹ ki emi ki o lọ nitori ti ojúmọ mọ́ tán. On si wipe, Emi ki yio jẹ ki iwọ ki o lọ, bikoṣepe iwọ ba sure fun mi. O si bi i pe, Orukọ rẹ? On si dahùn pe, Jakobu. O si wipe, A ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori. Jakobu si bi i o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, sọ orukọ rẹ fun mi. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi? o si sure fun u nibẹ̀. Jakobu si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Penieli: o ni, Nitori ti mo ri Ọlọrun li ojukoju, a si dá ẹmi mi si. Bi o si ti nkọja Penieli, õrùn là bá a, o si nmukun ni itan rẹ̀.
Kà Gẹn 32
Feti si Gẹn 32
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 32:22-31
10 Days
Wrestling with faith and doubt can be profoundly lonely and isolating. Some suffer in silence while others abandon belief altogether, assuming doubt is incompatible with faith. Dominic Done believes this is both tragic and deeply mistaken. He uses Scripture and literature to argue that not only is questioning normal but it is often a path toward a rich and vibrant faith. Explore faith and doubt in this 10-day plan.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò