Fun mi li awọn obinrin mi, ati awọn ọmọ mi, nitori awọn ẹniti mo ti nsìn ọ, ki o si jẹ ki nma lọ: iwọ sá mọ̀ ìsin ti mo sìn ọ. Labani si wipe, Duro, emi bẹ̀ ọ, bi o ba ṣepe emi ri ore-ọfẹ li oju rẹ, joko: nitori ti mo ri i pe, OLUWA ti bukún fun mi nitori rẹ. O si wi fun u pe, Sọ iye owo iṣẹ rẹ, emi o si fi fun ọ. O si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ bi emi ti sìn ọ, ati bi ẹran-ọ̀sin rẹ ti wà lọdọ mi. Diẹ ni iwọ sá ti ní ki nto dé ọdọ rẹ, OLUWA si busi i li ọ̀pọlọpọ fun ọ lati ìgba ti mo ti dé: njẹ nisisiyi nigbawo li emi o pèse fun ile mi? O si bi i pe, Kili emi o fi fun ọ? Jakobu si wi pe, Iwọ máṣe fun mi li ohun kan: bi iwọ o ba le ṣe eyi fun mi, emi o ma bọ́, emi o si ma ṣọ́ agbo-ẹran rẹ.
Kà Gẹn 30
Feti si Gẹn 30
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 30:26-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò