Gẹn 30:22-24

Gẹn 30:22-24 YBCV

Ọlọrun si ranti Rakeli, Ọlọrun si gbọ́ tirẹ̀, o si ṣí i ni inu. O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Ọlọrun mú ẹ̀gan mi kuro: O si pè orukọ rẹ̀ ni Josefu; o si wipe, Ki OLUWA ki o fi ọmọkunrin kan kún u fun mi pẹlu.