Gẹn 30:1-4

Gẹn 30:1-4 YBCV

NIGBATI Rakeli ri pe on kò bimọ fun Jakobu, Rakeli ṣe ilara arabinrin rẹ̀; o si wi fun Jakobu pe, Fun mi li ọmọ, bikoṣe bẹ̃ emi o kú. Jakobu si binu si Rakeli: o si wipe, Emi ha wà ni ipò Ọlọrun, ẹniti o dù ọ li ọmọ bíbi? On si wipe, Wò Bilha iranṣẹbinrin mi, wọle tọ̀ ọ; on ni yio si bí lori ẽkun mi, ki a le gbé mi ró pẹlu nipasẹ rẹ̀. O si fi Bilha, iranṣẹbinrin rẹ̀, fun u li aya: Jakobu si wọle tọ̀ ọ.