Gẹn 3:9-13

Gẹn 3:9-13 YBCV

OLUWA Ọlọrun si kọ si Adamu, o si wi fun u pe, Nibo ni iwọ wà? O si wipe, Mo gbọ́ ohùn rẹ ninu ọgbà, ẹ̀ru si bà mi, nitori ti mo wà ni ìhoho; mo si fi ara pamọ́. O si wi pe, Tali o wi fun ọ pe iwọ wà ni ìhoho? iwọ ha jẹ ninu igi nì, ninu eyiti mo paṣẹ fun ọ pe iwọ kò gbọdọ jẹ? Ọkunrin na si wipe, Obinrin ti iwọ fi pẹlu mi, on li o fun mi ninu eso igi na, emi si jẹ. OLUWA Ọlọrun si bi obinrin na pe, Ewo ni iwọ ṣe yi? Obinrin na si wipe, Ejò li o tàn mi, mo si jẹ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gẹn 3:9-13